-
Jóṣúà 21:34-40Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
34 Wọ́n fún ìdílé àwọn ọmọ Mérárì,+ àwọn ọmọ Léfì tó ṣẹ́ kù ní àwọn ìlú yìí látinú ìpín ẹ̀yà Sébúlúnì:+ Jókínéámù+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, Kárítà pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, 35 Dímúnà pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀ àti Náhálálì+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, ó jẹ́ ìlú mẹ́rin.
36 Látinú ìpín ẹ̀yà Rúbẹ́nì: Bésérì+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, Jáhásì pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀,+ 37 Kédémótì pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀ àti Mẹ́fáátì pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, ó jẹ́ ìlú mẹ́rin.
38 Látinú ìpín ẹ̀yà Gádì:+ ìlú ààbò tí ẹni tó bá pààyàn máa sá lọ, ìyẹn Rámótì ní Gílíádì+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, Máhánáímù+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, 39 Hẹ́ṣíbónì+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀ àti Jásérì+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, ó jẹ́ ìlú mẹ́rin.
40 Gbogbo ìlú tí wọ́n pín fún àwọn ọmọ Mérárì ní ìdílé-ìdílé, àwọn tó ṣẹ́ kù nínú ìdílé àwọn ọmọ Léfì jẹ́ ìlú méjìlá (12).
-