25Síwájú sí i, Dáfídì àti àwọn olórí àwùjọ àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìsìn ya àwọn kan lára àwọn ọmọ Ásáfù, Hémánì àti Jédútúnì+ sọ́tọ̀ láti máa fi háàpù, àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín+ àti síńbálì*+ sọ tẹ́lẹ̀. Orúkọ àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ ìsìn yìí ni,
3 Látinú Jédútúnì,+ àwọn ọmọ Jédútúnì ni: Gẹdaláyà, Séérì, Jeṣáyà, Ṣíméì, Haṣabáyà àti Matitáyà,+ wọ́n jẹ́ mẹ́fà lábẹ́ ìdarí bàbá wọn Jédútúnì, ẹni tó ń fi háàpù sọ tẹ́lẹ̀, láti máa dúpẹ́ àti láti máa yin Jèhófà.+