-
1 Kíróníkà 22:2-4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Dáfídì wá pàṣẹ pé kí wọ́n kó àwọn àjèjì+ tó wà ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì jọ, ó sì yàn wọ́n ṣe agbẹ́kùúta láti máa gé òkúta, kí wọ́n sì máa gbẹ́ òkúta tí wọ́n á fi kọ́ ilé Ọlọ́run tòótọ́.+ 3 Dáfídì tún pèsè irin tó pọ̀ gan-an láti fi ṣe ìṣó ilẹ̀kùn àwọn ẹnubodè àti àwọn ẹ̀mú,* bákan náà, ó pèsè bàbà tó pọ̀ débi pé kò ṣeé wọ̀n+ 4 àti ẹ̀là gẹdú kédárì+ tí kò níye, nítorí àwọn ọmọ Sídónì + àti àwọn ará Tírè+ kó ẹ̀là gẹdú kédárì tó pọ̀ gan-an wá fún Dáfídì.
-