-
1 Àwọn Ọba 6:33-35Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
33 Bẹ́ẹ̀ náà ni ó ṣe fi igi ahóyaya ṣe férémù ilẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà tẹ́ńpìlì,* igun rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sì dọ́gba.* 34 Ó fi igi júnípà ṣe ilẹ̀kùn méjì. Ilẹ̀kùn àkọ́kọ́ ní awẹ́ méjì tó ṣeé pa dé, ilẹ̀kùn kejì sì ní awẹ́ méjì tó ṣeé pa dé.+ 35 Ó gbẹ́ àwọn kérúbù, igi ọ̀pẹ àti ìtànná òdòdó, ó sì fi wúrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ bo gbogbo wọn.
-