10 Àmọ́, gbàrà tí Dáníẹ́lì gbọ́ pé wọ́n ti fọwọ́ sí àṣẹ náà, ó lọ sínú ilé rẹ̀, èyí tí yàrá orí òrùlé rẹ̀ ní fèrèsé tó ṣí sílẹ̀, tó kọjú sí ọ̀nà Jerúsálẹ́mù.+ Ẹ̀ẹ̀mẹta lójúmọ́ ló máa ń kúnlẹ̀ láti gbàdúrà, tó sì ń yin Ọlọ́run rẹ̀, bó ṣe máa ń ṣe ní gbogbo ìgbà ṣáájú àkókò yìí.