21 Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn èèyàn Júdà mú Asaráyà*+ tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún (16),+ wọ́n sì fi í jọba ní ipò Amasááyà bàbá rẹ̀.+22 Ó tún Élátì+ kọ́, ó sì dá a pa dà fún Júdà lẹ́yìn tí ọba* ti sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀.+
6 Ní àkókò yẹn, Résínì ọba Síríà gba Élátì + pa dà fún Édómù, lẹ́yìn náà, ó lé àwọn Júù* kúrò ní Élátì. Àwọn ọmọ Édómù wọ Élátì, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀ títí di òní yìí.