-
Nehemáyà 10:28, 29Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
28 Ìyókù àwọn èèyàn náà, ìyẹn àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì, àwọn aṣọ́bodè, àwọn akọrin, àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ńpìlì* àti gbogbo àwọn tó ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn èèyàn ilẹ̀ tó yí wọn ká kí wọ́n lè pa Òfin Ọlọ́run tòótọ́ mọ́,+ pẹ̀lú àwọn ìyàwó wọn, àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn ọmọbìnrin wọn, gbogbo àwọn tó ní ìmọ̀ àti òye,* 29 dara pọ̀ mọ́ àwọn arákùnrin wọn, àwọn olókìkí àárín wọn, wọ́n gégùn-ún, wọ́n sì búra pé wọ́n á máa rìn nínú Òfin Ọlọ́run tòótọ́, èyí tó wá nípasẹ̀ Mósè ìránṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ àti pé àwọn á rí i pé àwọn ń pa gbogbo àṣẹ Jèhófà Olúwa wa mọ́ àti àwọn ìdájọ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìlànà rẹ̀.
-