-
1 Àwọn Ọba 15:20-22Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 Bẹni-hádádì ṣe ohun tí Ọba Ásà sọ, ó rán àwọn olórí ọmọ ogun rẹ̀ láti gbéjà ko àwọn ìlú Ísírẹ́lì, wọ́n sì ṣá Íjónì,+ Dánì+ àti Ebẹli-bẹti-máákà balẹ̀ pẹ̀lú gbogbo Kínérétì àti gbogbo ilẹ̀ Náfútálì. 21 Nígbà tí Bááṣà gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló jáwọ́ nínú kíkọ́* Rámà, ó sì ń gbé ní Tírísà.+ 22 Ọba Ásà wá pe gbogbo Júdà, láìyọ ẹnì kankan sílẹ̀, wọ́n kó àwọn òkúta àti ẹ̀là gẹdú tó wà ní Rámà, tí Bááṣà fi ń kọ́lé, Ọba Ásà sì fi wọ́n kọ́* Gébà+ ní Bẹ́ńjámínì àti Mísípà.+
-