-
2 Kíróníkà 17:3-6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Jèhófà wà pẹ̀lú Jèhóṣáfátì nítorí pé ó rìn ní àwọn ọ̀nà tí Dáfídì+ baba ńlá rẹ̀ rìn nígbà àtijọ́, kò sì wá àwọn Báálì. 4 Ó wá Ọlọ́run bàbá rẹ̀,+ ó ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́,* kò sì hu ìwà tí Ísírẹ́lì ń hù.+ 5 Jèhófà fìdí ìjọba náà múlẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀;+ gbogbo Júdà ń mú ẹ̀bùn wá fún Jèhóṣáfátì, ó sì ní ọrọ̀ àti ògo tó pọ̀ gan-an.+ 6 Ó ní ìgboyà láti máa rìn ní àwọn ọ̀nà Jèhófà, kódà ó mú àwọn ibi gíga+ àti àwọn òpó òrìṣà*+ kúrò ní Júdà.
-