-
Ẹ́sírà 5:1, 2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Nígbà náà, wòlíì Hágáì+ àti wòlíì Sekaráyà+ ọmọ ọmọ Ídò+ sọ tẹ́lẹ̀ fún àwọn Júù tó wà ní Júdà àti ní Jerúsálẹ́mù, ní orúkọ Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ẹni tó ń darí wọn. 2 Ìgbà náà ni Serubábélì+ ọmọ Ṣéálítíẹ́lì àti Jéṣúà+ ọmọ Jèhósádákì bẹ̀rẹ̀ sí í tún ilé Ọlọ́run kọ́,+ èyí tó wà ní Jerúsálẹ́mù; àwọn wòlíì Ọlọ́run wà pẹ̀lú wọn, wọ́n sì ń tì wọ́n lẹ́yìn.+
-
-
Sekaráyà 6:15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Àwọn tó wà lọ́nà jíjìn yóò wá, wọ́n sì máa wà lára àwọn tí yóò kọ́ tẹ́ńpìlì Jèhófà.” Ẹ ó sì mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ló rán mi sí yín. Yóò sì rí bẹ́ẹ̀, tí ẹ bá fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run yín.’”
-