-
Dáníẹ́lì 4:34, 35Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
34 “Ní òpin àkókò yẹn,+ èmi Nebukadinésárì gbójú sókè ọ̀run, òye mi sì pa dà sínú mi; mo yin Ẹni Gíga Jù Lọ, mo sì fi ìyìn àti ògo fún Ẹni tó wà láàyè títí láé, torí àkóso tó wà títí láé ni àkóso rẹ̀, ìjọba rẹ̀ sì wà láti ìran dé ìran.+ 35 Kò ka gbogbo àwọn tó ń gbé ayé sí nǹkan kan, ohun tó bá sì wù ú ló ń ṣe láàárín àwọn ọmọ ogun ọ̀run àti àwọn tó ń gbé ayé. Kò sí ẹni tó lè dá a dúró*+ tàbí kó sọ fún un pé, ‘Kí lo ṣe yìí?’+
-