-
1 Kíróníkà 29:9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Inú àwọn èèyàn náà dùn pé wọ́n mú ọrẹ wá tinútinú, nítorí pé gbogbo ọkàn+ ni wọ́n fi mú ọrẹ náà wá fún Jèhófà, inú Ọba Dáfídì pẹ̀lú sì dùn gan-an.
-
-
Ẹ́sírà 7:14-16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Nítorí ọba àti àwọn agbani-nímọ̀ràn rẹ̀ méje ló rán ọ láti wádìí bóyá wọ́n ń pa Òfin Ọlọ́run rẹ, tó wà pẹ̀lú* rẹ mọ́ ní Júdà àti Jerúsálẹ́mù, 15 kí o sì kó fàdákà àti wúrà tí ọba àti àwọn agbani-nímọ̀ràn rẹ̀ fi ṣe ọrẹ àtinúwá fún Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ẹni tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù 16 pẹ̀lú gbogbo fàdákà àti wúrà tí o bá gbà* ní gbogbo ìpínlẹ̀* Bábílónì àti ẹ̀bùn tí àwọn èèyàn náà àti àwọn àlùfáà fi ṣe ọrẹ àtinúwá fún ilé Ọlọ́run wọn, èyí tó wà ní Jerúsálẹ́mù.+
-