-
Ẹ́kísódù 29:38Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
38 “Ohun tí ìwọ yóò fi rúbọ lórí pẹpẹ náà nìyí: ọmọ àgbò méjì tó jẹ́ ọlọ́dún kan lójoojúmọ́ títí lọ.+
-
-
Nọ́ńbà 29:12, 13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 “‘Ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù keje, kí ẹ ṣe àpéjọ mímọ́. Ẹ má ṣe iṣẹ́ agbára kankan, kí ẹ sì fi ọjọ́ méje+ ṣe àjọyọ̀ fún Jèhófà. 13 Kí ẹ mú akọ ọmọ màlúù mẹ́tàlá (13) wá pẹ̀lú àgbò méjì àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́rìnlá (14) tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan láti fi rú ẹbọ sísun,+ ọrẹ àfinásun tó máa mú òórùn dídùn* jáde sí Jèhófà. Kí ara gbogbo wọn dá ṣáṣá.+
-