-
Ẹ́sírà 10:14, 15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Ní báyìí, jọ̀wọ́, jẹ́ kí àwọn olórí wa ṣojú fún gbogbo ìjọ yìí;+ kí gbogbo àwọn tó wà nínú àwọn ìlú wa tí wọ́n ti fẹ́ àwọn aya àjèjì sì jáde wá ní àkókò tí a dá pẹ̀lú àwọn àgbààgbà àti àwọn onídàájọ́ ìlú kọ̀ọ̀kan, títí a ó fi yí ìbínú Ọlọ́run wa tó ń jó bí iná kúrò lórí wa, nítorí ọ̀ràn yìí.”
15 Àmọ́, Jónátánì ọmọ Ásáhélì àti Jaseáyà ọmọ Tíkífà ta ko ọ̀rọ̀ yìí, Méṣúlámù àti Ṣábétáì+ tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì sì tì wọ́n lẹ́yìn.
-