5 Lóòótọ́, o ti mú kí ọjọ́ ayé mi kéré;+
Gbogbo ọjọ́ ayé mi kò sì jẹ́ nǹkan kan lójú rẹ.+
Ní ti ọmọ èèyàn, bó tilẹ̀ dà bíi pé kò sí nínú ewu, bí èémí lásán ló rí.+ (Sélà)
6 Dájúdájú, bí òjìji ni ọmọ èèyàn ń rìn kiri.
Ó ń sáré kiri lórí òfo.
Ó ń kó ọrọ̀ jọ pelemọ láìmọ ẹni tó máa gbádùn rẹ̀.+