-
Nọ́ńbà 31:25-27Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
25 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: 26 “Ka iye ẹrù tí wọ́n kó bọ̀ láti ogun, kí o ka iye èèyàn tí wọ́n kó lẹ́rú àtàwọn ẹran; ìwọ àti àlùfáà Élíásárì àti àwọn olórí agbo ilé bàbá wọn nínú àpéjọ náà ni kí ẹ jọ kà á. 27 Pín ẹrù tí wọ́n kó bọ̀ láti ogun sí méjì, kí ìdá kan jẹ́ ti àwọn ọmọ ogun tí wọ́n lọ jagun, kí ìdá kejì sì jẹ́ ti gbogbo àwọn yòókù nínú àpéjọ+ náà.
-
-
Jóṣúà 10:12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Lọ́jọ́ tí Jèhófà ṣẹ́gun àwọn Ámórì níṣojú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ìgbà yẹn ni Jóṣúà sọ fún Jèhófà níṣojú Ísírẹ́lì pé:
-
-
Jóṣúà 10:16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Àmọ́ àwọn ọba márààrún sá lọ, wọ́n sì lọ fara pa mọ́ sí inú ihò àpáta ní Mákédà.+
-
-
Àwọn Onídàájọ́ 5:19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
Wọn ò kó+ fàdákà kankan lójú ogun.
-