21 Lẹ́yìn náà, Jèhófà rán áńgẹ́lì kan, ó sì pa gbogbo jagunjagun tó lákíkanjú + àti àwọn aṣáájú pẹ̀lú àwọn olórí nínú ibùdó ọba Ásíríà, tó fi di pé ìtìjú ló fi pa dà lọ sí ilẹ̀ rẹ̀. Nígbà tó yá, ó wọ ilé ọlọ́run rẹ̀, ibẹ̀ ni àwọn kan lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì ti fi idà pa á.+