12 Ní oṣù karùn-ún, ní ọjọ́ kẹwàá oṣù náà, ìyẹn, ní ọdún kọkàndínlógún Nebukadinésárì ọba Bábílónì, Nebusarádánì olórí ẹ̀ṣọ́, tó jẹ́ ẹmẹ̀wà ọba Bábílónì, wá sí Jerúsálẹ́mù.+ 13 Ó dáná sun ilé Jèhófà+ àti ilé ọba pẹ̀lú gbogbo ilé tó wà ní Jerúsálẹ́mù; ó sì tún sun gbogbo ilé ńlá.