-
Jóṣúà 9:18-20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 Àmọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò gbéjà kò wọ́n, torí pé àwọn ìjòyè àpéjọ náà ti fi Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì búra+ fún wọn. Gbogbo àpéjọ náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í kùn sí àwọn ìjòyè náà. 19 Ni gbogbo àwọn ìjòyè náà bá sọ fún gbogbo àpéjọ náà pé: “A ò lè pa wọ́n lára torí pé a ti fi Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì búra fún wọn. 20 Ohun tí a máa ṣe nìyí: A máa dá ẹ̀mí wọn sí, kí ìbínú má bàa wá sórí wa torí ìbúra tí a ṣe fún wọn.”+
-
-
Àwọn Onídàájọ́ 11:34, 35Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
34 Níkẹyìn, Jẹ́fútà dé sí ilé rẹ̀ ní Mísípà,+ wò ó! ọmọbìnrin rẹ̀ ló ń jáde bọ̀ wá pàdé rẹ̀, ó ń lu ìlù tanboríìnì, ó sì ń jó! Òun ni ọmọ kan ṣoṣo tó bí. Kò ní ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin míì. 35 Nígbà tó rí i, ó fa aṣọ ara rẹ̀ ya, ó sì sọ pé: “Áà, ọmọbìnrin mi! O ti mú kí ọkàn mi bà jẹ́,* torí ìwọ ni ẹni tí màá ní kó lọ. Mo ti la ẹnu mi sí Jèhófà, mi ò sì lè yí i pa dà.”+
-