-
Jẹ́nẹ́sísì 22:15-18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Áńgẹ́lì Jèhófà tún pe Ábúráhámù lẹ́ẹ̀kejì láti ọ̀run, 16 ó sọ pé: “‘Mo fi ara mi búra pé torí ohun tí o ṣe yìí,’ ni Jèhófà+ wí, ‘tí o kò kọ̀ láti fún mi ní ọmọ rẹ, ọ̀kan ṣoṣo+ tí o ní, 17 ó dájú pé màá bù kún ọ, ó sì dájú pé màá mú kí ọmọ* rẹ pọ̀ bí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti iyanrìn etí òkun,+ ọmọ* rẹ yóò sì gba ẹnubodè* àwọn ọ̀tá+ rẹ̀ lọ́wọ́ wọn. 18 Gbogbo orílẹ̀-èdè tó wà láyé yóò gba ìbùkún fún ara wọn nípasẹ̀ ọmọ*+ rẹ torí pé o fetí sí ohùn+ mi.’”
-