-
Nọ́ńbà 16:5-7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Ó sì sọ fún Kórà àti gbogbo àwọn tó ń tì í lẹ́yìn pé: “Tó bá di àárọ̀, Jèhófà máa jẹ́ ká mọ ẹni tó jẹ́ tirẹ̀+ àti ẹni tó jẹ́ mímọ́ àti ẹni tó gbọ́dọ̀ máa sún mọ́ ọn,+ ẹnikẹ́ni tó bá sì yàn+ ló máa sún mọ́ ọn. 6 Ohun tí ẹ máa ṣe nìyí: Kí ìwọ Kórà àti gbogbo àwọn tó ń tì ọ́ lẹ́yìn+ mú ìkóná,+ 7 kí ẹ fi iná sí i, kí ẹ sì fi tùràrí sí i níwájú Jèhófà lọ́la, ẹni tí Jèhófà bá sì yàn,+ òun ni ẹni mímọ́. “Ó tó gẹ́ẹ́, ẹ̀yin ọmọ Léfì!”+
-