9 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹrú ni wá,+ Ọlọ́run wa kò fi wá sílẹ̀ nínú ipò ẹrú tí a wà; àmọ́ ó ti fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn sí wa níwájú àwọn ọba Páṣíà,+ láti gbé wa dìde kí a lè kọ́ ilé Ọlọ́run wa,+ kí a sì tún àwọn ibi tó ti di àwókù ṣe, kí ó sì fún wa ní odi ààbò ní Júdà àti ní Jerúsálẹ́mù.