-
Hébérù 12:9-11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Bákan náà, àwọn bàbá tó bí wa* máa ń bá wa wí, a sì máa ń bọ̀wọ̀ fún wọn. Ṣé kò wá yẹ kó yá wa lára láti fi ara wa sábẹ́ Baba tó ni ìgbésí ayé wa nípa ti ẹ̀mí, ká lè máa wà láàyè?+ 10 Torí ìgbà díẹ̀ ni wọ́n fi ń bá wa wí, bó ṣe dáa lójú wọn, àmọ́ torí ire wa ni òun ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, ká lè pín nínú ìjẹ́mímọ́ rẹ̀.+ 11 Lóòótọ́, kò sí ìbáwí tó jẹ́ ohun ayọ̀ báyìí, àmọ́ ó máa ń dunni;* síbẹ̀, tó bá yá, ó máa ń so èso àlàáfíà ti òdodo fún àwọn tí a ti fi dá lẹ́kọ̀ọ́.
-