11 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bá ara wọn kọrin,+ wọ́n ń yin Jèhófà, wọ́n sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, “nítorí ó jẹ́ ẹni rere; ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tó ní sí Ísírẹ́lì sì wà títí láé.”+ Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn èèyàn kígbe sókè láti yin Jèhófà nítorí wọ́n ti fi ìpìlẹ̀ ilé Jèhófà lélẹ̀.