29 “Ẹ kó àwọn tafàtafà jọ láti gbéjà ko Bábílónì,
Gbogbo àwọn tó ń tẹ ọrun.+
Ẹ pàgọ́ yí i ká; kí ẹnikẹ́ni má ṣe sá àsálà.
Ẹ san án fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.+
Bí ó ti ṣe sí àwọn èèyàn ni kí ẹ ṣe sí i gẹ́lẹ́.+
Nítorí pé ó ti gbéra ga sí Jèhófà,
Sí Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.+