-
1 Sámúẹ́lì 19:4, 5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Torí náà, Jónátánì sọ̀rọ̀ Dáfídì ní rere+ níwájú Sọ́ọ̀lù bàbá rẹ̀. Ó sọ fún un pé: “Kí ọba má ṣàìdáa sí* Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ̀, nítorí kò ṣẹ̀ ọ́, àwọn ohun tó ṣe fún ọ sì ti ṣe ọ́ láǹfààní. 5 Ó fi ẹ̀mí rẹ̀ wewu* kó lè pa Filísínì náà,+ tí Jèhófà sì mú kí gbogbo Ísírẹ́lì ṣẹ́gun* lọ́nà tó kàmàmà. O rí i, inú rẹ sì dùn gan-an. Kí ló wá dé tí o fẹ́ fi pa Dáfídì láìnídìí, tí wàá sì ní ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ lọ́rùn?”+
-