7 Àmọ́ ẹ̀yin tí ẹ̀ ń ní ìpọ́njú máa rí ìtura gbà pẹ̀lú wa nígbà ìfihàn Jésù Olúwa+ láti ọ̀run pẹ̀lú àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ alágbára+ 8 nínú iná tó ń jó fòfò, bó ṣe ń mú ẹ̀san wá sórí àwọn tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí kò ṣègbọràn sí ìhìn rere nípa Jésù Olúwa wa.+