Àìsáyà 11:4 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 4 Ó máa dá ẹjọ́ àwọn ẹni rírẹlẹ̀ bó ṣe tọ́,*Ó sì máa fi òtítọ́ báni wí torí àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ tó wà ní ayé. Ó máa fi ọ̀pá ẹnu rẹ̀ lu ayé,+Ó sì máa fi èémí* ètè rẹ̀ pa ẹni burúkú.+ Jeremáyà 33:15 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 15 Nígbà yẹn àti ní àkókò yẹn, màá mú kí èéhù* òdodo kan hù jáde fún Dáfídì,+ á sì ṣe ìdájọ́ tí ó tọ́ àti òdodo ní ilẹ̀ náà.+ Hébérù 1:8, 9 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 8 Àmọ́, ó sọ nípa Ọmọ pé: “Ọlọ́run ni ìtẹ́ rẹ+ títí láé àti láéláé, ọ̀pá àṣẹ Ìjọba rẹ sì jẹ́ ọ̀pá àṣẹ ìdúróṣinṣin.* 9 O nífẹ̀ẹ́ òdodo, o sì kórìíra ìwà tí kò bófin mu. Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ, fi fòróró ayọ̀ yàn ọ́+ ju àwọn ojúgbà rẹ.”+
4 Ó máa dá ẹjọ́ àwọn ẹni rírẹlẹ̀ bó ṣe tọ́,*Ó sì máa fi òtítọ́ báni wí torí àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ tó wà ní ayé. Ó máa fi ọ̀pá ẹnu rẹ̀ lu ayé,+Ó sì máa fi èémí* ètè rẹ̀ pa ẹni burúkú.+
15 Nígbà yẹn àti ní àkókò yẹn, màá mú kí èéhù* òdodo kan hù jáde fún Dáfídì,+ á sì ṣe ìdájọ́ tí ó tọ́ àti òdodo ní ilẹ̀ náà.+
8 Àmọ́, ó sọ nípa Ọmọ pé: “Ọlọ́run ni ìtẹ́ rẹ+ títí láé àti láéláé, ọ̀pá àṣẹ Ìjọba rẹ sì jẹ́ ọ̀pá àṣẹ ìdúróṣinṣin.* 9 O nífẹ̀ẹ́ òdodo, o sì kórìíra ìwà tí kò bófin mu. Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ, fi fòróró ayọ̀ yàn ọ́+ ju àwọn ojúgbà rẹ.”+