21 Gbà mí kúrò lẹ́nu kìnnìún + àti lọ́wọ́ ìwo akọ màlúù igbó;
Dá mi lóhùn, kí o sì gbà mí sílẹ̀.
22 Màá sọ orúkọ rẹ fún àwọn arákùnrin mi;+
Màá sì yìn ọ́ láàárín ìjọ.+
23 Ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù Jèhófà, ẹ yìn ín!
Gbogbo ẹ̀yin ọmọ Jékọ́bù, ẹ yìn ín lógo!+
Ẹ máa bẹ̀rù rẹ̀, gbogbo ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì.