10 Wò ó, idà kò ní kúrò ní ilé rẹ láé,+ nítorí pé o kọ̀ mí, tí o sì sọ ìyàwó Ùráyà ọmọ Hétì di tìrẹ.’ 11 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: ‘Wò ó, màá mú kí àjálù bá ọ láti inú ilé ara rẹ;+ ojú rẹ ni màá ti gba àwọn ìyàwó rẹ,+ tí màá fi wọ́n fún ọkùnrin míì, tí á sì bá wọn sùn ní ọ̀sán gangan.+