39 Nígbà tí Dáfídì gbọ́ pé Nábálì ti kú, ó sọ pé: “Ẹ yin Jèhófà, ẹni tí ó bá mi dá ẹjọ́ mi+ nítorí àbùkù tí Nábálì fi kàn mí,+ tí kò sì jẹ́ kí ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣe ohun búburú,+ Jèhófà sì ti mú kí ibi Nábálì dà lé e lórí!” Dáfídì wá ránṣẹ́ sí Ábígẹ́lì pé kó wá di ìyàwó òun.
3 Kí ẹwà yín má ṣe jẹ́ ti òde ara, bí irun dídì, wíwọ àwọn ohun ọ̀ṣọ́ wúrà+ tàbí wíwọ àwọn aṣọ olówó ńlá, 4 àmọ́ kó jẹ́ ti ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn, kí ẹ fi ìwà jẹ́jẹ́ àti ìwà tútù ṣe ọ̀ṣọ́ tí kò lè bà jẹ́,+ èyí tó níye lórí gan-an lójú Ọlọ́run.