7 Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín jẹ: Ọlọ́run kò ṣeé tàn. Nítorí ohun tí èèyàn bá gbìn, òun ló máa ká;+ 8 torí pé ẹni tó bá ń fúnrúgbìn nítorí ara rẹ̀ máa ká ìdíbàjẹ́ látinú ara rẹ̀, àmọ́ ẹni tó bá ń fúnrúgbìn nítorí ẹ̀mí máa ká ìyè àìnípẹ̀kun látinú ẹ̀mí.+