-
Rúùtù 1:16, 17Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Àmọ́ Rúùtù sọ pé: “Má rọ̀ mí pé kí n fi ọ́ sílẹ̀, pé kí n má ṣe bá ọ lọ; torí ibi tí o bá lọ ni èmi yóò lọ, ibi tí o bá sùn ni èmi yóò sùn. Àwọn èèyàn rẹ ni yóò jẹ́ èèyàn mi, Ọlọ́run rẹ ni yóò sì jẹ́ Ọlọ́run mi.+ 17 Ibi tí o bá kú sí ni èmi yóò kú sí, ibẹ̀ sì ni wọn yóò sin mí sí. Kí Jèhófà fi ìyà jẹ mí gan-an bí ohunkóhun yàtọ̀ sí ikú bá yà wá.”
-
-
1 Sámúẹ́lì 19:2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Nítorí pé Jónátánì ọmọ Sọ́ọ̀lù nífẹ̀ẹ́ Dáfídì+ gan-an, ó sọ fún Dáfídì pé: “Sọ́ọ̀lù bàbá mi fẹ́ pa ọ́. Jọ̀wọ́ múra láàárọ̀ ọ̀la, sá lọ sí ibi ìkọ̀kọ̀ kan, kí o sì fara pa mọ́ síbẹ̀.
-