Diutarónómì 8:5 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 5 O mọ̀ dáadáa lọ́kàn rẹ pé bí bàbá ṣe ń tọ́ ọmọ rẹ̀ sọ́nà ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń tọ́ ọ sọ́nà.+ Hébérù 12:7 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 7 Ẹ nílò ìfaradà bí ẹ ṣe ń gba ìbáwí.* Ọlọ́run mú yín bí ọmọ.+ Torí ọmọ wo ni bàbá kì í bá wí?+ Hébérù 12:9 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 9 Bákan náà, àwọn bàbá tó bí wa* máa ń bá wa wí, a sì máa ń bọ̀wọ̀ fún wọn. Ṣé kò wá yẹ kó yá wa lára láti fi ara wa sábẹ́ Baba tó ni ìgbésí ayé wa nípa ti ẹ̀mí, ká lè máa wà láàyè?+
9 Bákan náà, àwọn bàbá tó bí wa* máa ń bá wa wí, a sì máa ń bọ̀wọ̀ fún wọn. Ṣé kò wá yẹ kó yá wa lára láti fi ara wa sábẹ́ Baba tó ni ìgbésí ayé wa nípa ti ẹ̀mí, ká lè máa wà láàyè?+