-
Jẹ́nẹ́sísì 37:9-11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Lẹ́yìn ìyẹn, ó tún lá àlá míì, ó sì rọ́ ọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀, ó ní: “Mo tún lá àlá míì. Lọ́tẹ̀ yìí, oòrùn àti òṣùpá àti ìràwọ̀ mọ́kànlá (11) ń tẹrí ba fún mi.”+ 10 Ó rọ́ ọ fún bàbá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀, bàbá rẹ̀ sì bá a wí, ó ní: “Kí ni ìtúmọ̀ àlá tí o lá yìí? Ṣé èmi àti ìyá rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ yóò wá máa tẹrí ba mọ́lẹ̀ fún ọ ni?” 11 Àwọn arákùnrin rẹ̀ wá bẹ̀rẹ̀ sí í jowú rẹ̀,+ àmọ́ bàbá rẹ̀ fi ọ̀rọ̀ náà sọ́kàn.
-