-
1 Sámúẹ́lì 15:13-15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Níkẹyìn, Sámúẹ́lì dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, Sọ́ọ̀lù sì sọ fún un pé: “Kí Jèhófà bù kún ọ. Mo ti ṣe ohun tí Jèhófà sọ.” 14 Àmọ́ Sámúẹ́lì sọ pé: “Kí wá ni ohùn agbo ẹran tó ń dún yìí àti ohùn ọ̀wọ́ ẹran tí mò ń gbọ́ yìí?”+ 15 Ni Sọ́ọ̀lù bá sọ pé: “Ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ámálékì ni wọ́n ti mú wọn wá, nítorí àwọn èèyàn náà dá agbo ẹran àti ọ̀wọ́ ẹran tó dára jù sí,* láti fi wọ́n rúbọ sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ; àmọ́ a ti pa àwọn ohun tó ṣẹ́ kù run.”
-