15 Ẹni tí kò jáwọ́ nínú ṣíṣe òdodo,+
Tó ń sọ ohun tó tọ́,+
Tó kọ àìṣòótọ́ àti èrè jìbìtì,
Tí ọwọ́ rẹ̀ kọ àbẹ̀tẹ́lẹ̀ dípò kó gbà á,+
Tó ń di etí rẹ̀ sí ọ̀rọ̀ ìtàjẹ̀sílẹ̀,
Tó sì ń di ojú rẹ̀ kó má bàa rí ohun tó burú
16 —Ó máa gbé ní àwọn ibi gíga;
Ibi ààbò rẹ̀ máa wà níbi àwọn àpáta tó láàbò,
Á máa rí oúnjẹ jẹ,
Omi ò sì ní wọ́n ọn láé.”+