-
Oníwàásù 5:18, 19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 Ohun tí mo rí pé ó dára tí ó sì tọ́ ni pé: kéèyàn máa jẹ, kó máa mu, kó sì jẹ ìgbádùn gbogbo iṣẹ́ àṣekára+ tó fi gbogbo agbára rẹ̀ ṣe lábẹ́ ọ̀run* láàárín ọjọ́ díẹ̀ tí Ọlọ́run tòótọ́ fún un, nítorí èrè* rẹ̀ nìyẹn.+ 19 Bákan náà, nígbà tí Ọlọ́run tòótọ́ bá fún ẹnì kan ní ọrọ̀ àti ohun ìní,+ tó sì jẹ́ kó lè gbádùn wọn, kí ẹni náà gba èrè* rẹ̀ kó sì máa yọ̀ nínú iṣẹ́ àṣekára rẹ̀. Ẹ̀bùn Ọlọ́run ni èyí.+
-