-
Ẹ́kísódù 30:23Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
23 “Lẹ́yìn náà, kí o mú àwọn lọ́fínńdà tó dáa jù: ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) ìwọ̀n òjíá dídì àti sínámónì dídùn tó jẹ́ ìdajì rẹ̀, ìyẹn igba ó lé àádọ́ta (250) ìwọ̀n àti igba ó lé àádọ́ta (250) ìwọ̀n ewéko kálámọ́sì dídùn
-
-
Ẹ́sítà 2:12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọ̀dọ́bìnrin náà ló ní ìgbà tí wọ́n máa wọlé sọ́dọ̀ Ọba Ahasuérúsì lẹ́yìn tí wọ́n bá ti parí ìtọ́jú olóṣù méjìlá tí wọ́n ní kí wọ́n fún àwọn obìnrin, nítorí ohun tí ìtọ́jú aṣaralóge* náà gbà nìyẹn, wọ́n á fi oṣù mẹ́fà lo òróró òjíá,+ wọ́n á sì fi oṣù mẹ́fà lo òróró básámù+ pẹ̀lú oríṣiríṣi òróró ìpara tí wọ́n fi ń ṣe ìtọ́jú aṣaralóge.*
-
-
Sáàmù 45:8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Òjíá àti álóè àti kaṣíà ń já fíkán lára gbogbo aṣọ rẹ;
Ìró àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín látinú ààfin títóbi lọ́lá tí a fi eyín erin ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ ń mú inú rẹ dùn.
-