18 Kí ni àǹfààní ère,
Nígbà tó jẹ́ pé èèyàn ló gbẹ́ ẹ?
Kí ni àǹfààní ère onírin àti olùkọ́ èké,
Tí ẹni tó ṣe é bá tiẹ̀ gbẹ́kẹ̀ lé e,
Tó ṣe àwọn ọlọ́run tí kò ní láárí, tí kò lè sọ̀rọ̀?+
19 O gbé, ìwọ tí ò ń sọ fún igi pé: “Dìde!”
Tàbí fún òkúta tí kò lè sọ̀rọ̀ pé: “Gbéra nílẹ̀! Máa kọ́ wa!”
Wò ó! Wúrà àti fàdákà ni wọ́n fi bò ó,+
Kò sì sí èémí kankan nínú rẹ̀.+