-
Nehemáyà 9:34, 35Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
34 Ní ti àwọn ọba wa, àwọn ìjòyè wa, àwọn àlùfáà wa àti àwọn baba ńlá wa, wọn ò pa Òfin rẹ mọ́, wọn ò sì fiyè sí àwọn àṣẹ rẹ tàbí àwọn ìránnilétí* rẹ tí o fi kìlọ̀ fún wọn. 35 Kódà nígbà tí wọ́n wà lábẹ́ ìjọba ti ara wọn, tí wọ́n sì ń gbádùn ọ̀pọ̀ ohun rere tí o fún wọn, tí wọ́n ń gbé lórí ilẹ̀ tó fẹ̀, tó sì lọ́ràá* tí o fi jíǹkí wọn, wọn ò sìn ọ́,+ wọn ò sì jáwọ́ nínú ìwà búburú tí wọ́n ń hù.
-
-
Dáníẹ́lì 9:8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 “Jèhófà, àwa ni ìtìjú bá, àwọn ọba wa, àwọn ìjòyè wa àti àwọn baba ńlá wa, torí pé a ti ṣẹ̀ ọ́.
-