10 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,
Ẹ sì kéde rẹ̀ láàárín àwọn erékùṣù tó jìnnà réré pé:+
“Ẹni tó tú Ísírẹ́lì ká máa kó o jọ.
Á máa bójú tó o bí olùṣọ́ àgùntàn ṣe ń bójú tó agbo ẹran rẹ̀.+
11 Nítorí Jèhófà máa ra Jékọ́bù pa dà+
Á sì gbà á lọ́wọ́ ẹni tó lágbára jù ú lọ.+