24 Ta ló ti mú kí wọ́n kó ohun ìní Jékọ́bù,
Tó sì mú kí wọ́n kó ẹrù Ísírẹ́lì?
Ṣebí Jèhófà ni, Ẹni tí a ṣẹ̀?
Wọ́n kọ̀ láti rìn ní àwọn ọ̀nà Rẹ̀,
Wọn ò sì ṣègbọràn sí òfin Rẹ̀.+
25 Torí náà, Ó ń da ìhónú lé e lórí,
Ìrunú rẹ̀ àti ìbínú ogun.+
Ó jẹ gbogbo ohun tó yí i ká run, àmọ́ kò fiyè sí i.+
Ó jó o, àmọ́ kò fọkàn sí i.+