-
Lúùkù 1:30-35Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
30 Áńgẹ́lì náà wá sọ fún un pé: “Má bẹ̀rù, Màríà, torí o ti rí ojúure Ọlọ́run. 31 Wò ó! o máa lóyún,* o sì máa bí ọmọkùnrin kan,+ kí o pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù.+ 32 Ẹni yìí máa jẹ́ ẹni ńlá,+ wọ́n á máa pè é ní Ọmọ Ẹni Gíga Jù Lọ,+ Jèhófà* Ọlọ́run sì máa fún un ní ìtẹ́ Dáfídì bàbá rẹ̀,+ 33 ó máa jẹ Ọba lórí ilé Jékọ́bù títí láé, Ìjọba rẹ̀ ò sì ní lópin.”+
34 Àmọ́ Màríà sọ fún áńgẹ́lì náà pé: “Báwo ló ṣe máa ṣẹlẹ̀, nígbà tó jẹ́ pé mi ò bá ọkùnrin lò pọ̀?”+ 35 Áńgẹ́lì náà dá a lóhùn pé: “Ẹ̀mí mímọ́ máa bà lé ọ,+ agbára Ẹni Gíga Jù Lọ sì máa ṣíji bò ọ́. Ìdí nìyẹn tí a fi máa pe ẹni tí o bí ní mímọ́,+ Ọmọ Ọlọ́run.+
-