3 Kí tafàtafà má lè tẹ ọrun rẹ̀.
Kí ẹnikẹ́ni tó wọ ẹ̀wù irin má sì lè nàró.
Ẹ má ṣàánú àwọn ọ̀dọ́kùnrin rẹ̀.+
Ẹ pa gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ run pátápátá.
4 Wọ́n á ṣubú, wọ́n á sì kú ní ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà,
A ó sì gún wọn ní àgúnyọ ní àwọn ojú ọ̀nà rẹ̀.+