8 ‘Nítorí náà, ẹ máa retí mi,’+ ni Jèhófà wí,
‘Títí di ọjọ́ tí màá wá gba ohun tí ẹ ti gbà lọ́wọ́ àwọn èèyàn,
Nítorí ìdájọ́ mi ni láti kó àwọn orílẹ̀-èdè jọ, kí n sì kó àwọn ìjọba jọ,
Kí n lè da ìrunú mi sórí wọn, gbogbo ìbínú mi tó ń jó fòfò;+
Torí ìtara mi tó ń jó bí iná máa jó gbogbo ayé run.+