-
Jóṣúà 10:29, 30Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
29 Jóṣúà àti gbogbo Ísírẹ́lì wá kúrò ní Mákédà lọ sí Líbínà, wọ́n sì bá Líbínà+ jà. 30 Jèhófà tún fi ìlú náà àti ọba rẹ̀+ lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́, wọ́n sì fi idà pa ìlú náà run àti gbogbo àwọn* tó ń gbé ibẹ̀, wọn ò ṣẹ́ ẹnì kankan kù níbẹ̀. Ohun tí wọ́n ṣe sí ọba Jẹ́ríkò+ gẹ́lẹ́ ni wọ́n ṣe sí ọba ìlú náà.
-
-
2 Àwọn Ọba 8:22Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
22 Àmọ́ Édómù ṣì ń ṣọ̀tẹ̀ sí Júdà títí di òní yìí. Líbínà+ pẹ̀lú ṣọ̀tẹ̀ ní àkókò yẹn.
-
-
2 Àwọn Ọba 19:8-13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Lẹ́yìn tí Rábúṣákè gbọ́ pé ọba Ásíríà ti kúrò ní Lákíṣì,+ ó pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì rí i tó ń bá Líbínà jà.+ 9 Ọba wá gbọ́ tí wọ́n sọ nípa Tíhákà ọba Etiópíà pé: “Wò ó, ó ti jáde láti wá bá ọ jà.” Nítorí náà, ó tún rán àwọn òjíṣẹ́+ sí Hẹsikáyà pé: 10 “Ẹ sọ fún Hẹsikáyà ọba Júdà pé, ‘Má ṣe jẹ́ kí Ọlọ́run rẹ tí o gbẹ́kẹ̀ lé tàn ọ́ jẹ pé: “A kò ní fi Jerúsálẹ́mù lé ọba Ásíríà lọ́wọ́.”+ 11 Wò ó! O ti gbọ́ ohun tí àwọn ọba Ásíríà ṣe sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, bí wọ́n ṣe pa wọ́n run.+ Ṣé o rò pé o lè bọ́ lọ́wọ́ wa ni? 12 Ǹjẹ́ àwọn ọlọ́run àwọn orílẹ̀-èdè tí àwọn baba ńlá mi pa run gbà wọ́n? Ibo ni Gósánì, Háránì,+ Réséfù àti àwọn èèyàn Édẹ́nì tó wà ní Tẹli-ásárì wà? 13 Ibo ni ọba Hámátì, ọba Áápádì, ọba àwọn ìlú Séfáfáímù, ọba Hénà àti ọba Ífà+ wà?’”
-