-
Jeremáyà 40:11, 12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Gbogbo àwọn Júù tó wà ní Móábù, ní Ámónì àti ní Édómù títí kan àwọn tó wà ní gbogbo àwọn ilẹ̀ yòókù náà gbọ́ pé ọba Bábílónì ti fi àwọn kan sílẹ̀ kí wọ́n máa gbé ní Júdà àti pé ó ti yan Gẹdaláyà ọmọ Áhíkámù ọmọ Ṣáfánì ṣe olórí wọn. 12 Torí náà gbogbo àwọn Júù bẹ̀rẹ̀ sí í pa dà wá láti gbogbo ibi tí wọ́n fọ́n wọn ká sí, wọ́n sì wá sí ilẹ̀ Júdà, sọ́dọ̀ Gẹdaláyà ní Mísípà. Wọ́n sì kó wáìnì àti èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn jọ lọ́pọ̀lọpọ̀.
-