-
Jeremáyà 5:19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
19 Tí wọ́n bá sì béèrè pé, ‘Kí ló dé tí Jèhófà Ọlọ́run wa fi ṣe gbogbo nǹkan yìí sí wa?’ kí o sọ fún wọn pé, ‘Bí ẹ ṣe fi mí sílẹ̀ láti sin ọlọ́run àjèjì ní ilẹ̀ yín, bẹ́ẹ̀ ni ẹ ó sin àwọn àjèjì ní ilẹ̀ kan tí kì í ṣe tiyín.’”+
-
-
Jeremáyà 16:10, 11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 “Nígbà tí o bá sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí fún àwọn èèyàn yìí, wọ́n á béèrè lọ́wọ́ rẹ pé, ‘Kí nìdí tí Jèhófà fi sọ pé kí gbogbo àjálù ńlá yìí dé bá wa? Kí la ṣe, ẹ̀ṣẹ̀ wo la ṣẹ Jèhófà Ọlọ́run wa?’+ 11 Kí o fún wọn lésì pé, ‘“Nítorí pé àwọn baba ńlá yín fi mí sílẹ̀,”+ ni Jèhófà wí, “wọ́n ń tẹ̀ lé àwọn ọlọ́run míì, wọ́n ń sìn wọ́n, wọ́n sì ń forí balẹ̀ fún wọn.+ Ńṣe ni wọ́n fi mí sílẹ̀, wọn kò sì pa òfin mi mọ́.+
-