16 “Ọmọ èèyàn, mo máa tó mú ẹni tí o fẹ́ràn kúrò lọ́dọ̀ rẹ lójijì.+ Má ṣe ṣọ̀fọ̀; má ṣe sunkún, má sì da omi lójú. 17 Banú jẹ́, àmọ́ má ṣe jẹ́ kó hàn síta, má tẹ̀ lé àṣà àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ òkú.+ Wé láwàní rẹ,+ kí o sì wọ bàtà rẹ.+ Má bo ẹnu rẹ,+ má sì jẹ oúnjẹ tí àwọn ẹlòmíì bá gbé wá fún ọ.”+